King Sunny Ade - Ara Ma Nfe Sinmi paroles de chanson

paroles de chanson Ara Ma Nfe Sinmi - King Sunny Ade



Ọrẹ rẹ die bínú bínú woni mo ku
Iya gbó ni ebi ń kiri
Iya gbó ni ọrẹ ń kiri
Tebi Tara tore, won temi lago
Lai mo wípé
Mi ò báwọn wá, mi ò báwọn lo
Mi ò báwọn wá, mi ò báwọn lo
Ototo larin wá, Ototo larin
Ṣebi ile ayé, ilé ayé, ilé ayé pàdé ara wa
Ọrẹ wá, ọjọ' lọ npe ó, Ìpàdé kìí jinna
ọjọ' lọ npe ó, Ìpàdé kìí jinna
Ìkà eda fowo padà Ọlọ'run loju
Ìkà eda fowo padà Ọlọ'run loju
Ìdájọ' ó jìnnà, idajo ó jìnnà
Aye dalekun
Torí mi ò báwọn wá, èmi ò báwọn lo
Mi ò báwọn wá, èmi ó báwọn lo
Torí, òtoto larin wa, òtoto larin
Ṣebi ile ayé, ilé ayé, ilé ayé pàdé ara wa
Ayéeeeeeee, Ayee yiii oooo
Ayéeeeeeee, Ayee yiii oooo
Ayé toto
Ọjọ' ó rò, ìṣù ó tà, àgbàdo ó gbó oo
Ọjọ' ó rò, ìṣù ó tà, àgbàdo ó gbó oo
Ọjọ' ó se, ìṣù ó tà, àgbàdo ó gbó oo
Ara máa ń fẹ', (ara máa ń fẹ' simi)
E rọra ṣe (ara máa ń fẹ' simi)
E rọra (ara máa ń fẹ' simi)
Ara máa ń fẹẹ (ara máa ń fẹ' simi)
Àní ara máa ń fẹ' ó jare (ara máa ń fẹ' simi)
Jìgìjìgì lojojumo (ara máa ń fẹ' simi)
Ọrẹ jìgìjìgì lojojumo (ara máa ń fẹ' simi)
Ifakafiki làálàá (ara máa ń fẹ' simi)
Jìgìjìgì lojojumo (ara máa ń fẹ' simi)
Ará máa ń fẹ' ó jare (ara máa ń fẹ' simi)
Ifakafiki lórí ẹni (ara máa ń fẹ' simi)
Ará máa ń fẹ' (ara máa ń fẹ' simi)
(End.)



Writer(s): King Sunny Ade


King Sunny Ade - E Dide (Get Up)
Album E Dide (Get Up)
date de sortie
29-07-2008




Attention! N'hésitez pas à laisser des commentaires.